From ÌGBỌ̀NRÌRÌ

From ÌGBỌ̀NRÌRÌ

Chimamanda Adichie

(Ìtumọ̀ láti ọwọ́ Kọ́lá Túbọ̀sún)

 

Ukamaka gbé fóònù alágbèéká ẹ̀, ó dúró sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan, ó sì wòó. Rachel, ọ̀rẹ́ ẹ̀ kan láti kíláàsì ẹ̀ ni, bóyá ó ń pè láti mọ̀ bóyá ó fẹ́ lọ gbọ́ ọ̀rọ̀ lóríi ìhùwàsí àti kíkọ̀wẹ́ ìtàn ní East Pyne lọ́jọ́ kejì.

‘Mi ò tiẹ̀ gbàgbọ́ pé Udenna ò tíì pè mí,’ Ukamaka sọ, ó sì tanná sí mọ́tò. Udenna ti fi ìfirahnṣẹ́ ayárabíàṣá ránṣẹ́ síi láti dúpẹ́ lọ́wọ́ ẹ̀ fún ìkọbiarasíi ẹ̀ nígbà t’óun wà ní Nigeria. Ó ti yọ Ukamaka kúrò nínú àwọn ọ̀rẹ́ẹ̀ ní Instant Messenger tí kò fi ní le mọ̀ tí ó bá wà lórí ayélujára. Kò sì tíì pè.

‘Bóyá ó tiẹ̀ dáa kó má pè,’ Chinedu sọ. ‘Kóo baà lè tẹ̀síwájú.’

Ukamaka dúró títí wọ́n fi padà dé inúu ibùgbée wọn, tí Chinedu sì ti gbé àwọ àpòo è lọ sínú ilé tó sì ti padà sọ̀kalẹ̀ wá, kó tó ní, ‘Ṣé o mọ̀, kò rọrùn tó bóo ṣe ròó yẹn o. Oò mọ bó ṣe rí láti nífẹ̀ẹ́ olóríburúkú kan.’

‘Mo mọ̀ o.’

Ó wòó, ó wọ aṣọ kannáà tó wọ̀ lọ́sàn ijọ́ tó kọ́kọ́ kànlẹ̀kùun ẹ: jínsì àti swẹ́tà kan tó rọ̀ lọ́rùn, tí wọ́n kọ Princeton sí lára, ní àwọ̀ ọsàn.

‘Oò tíì sọ ǹkankan nípa ẹ̀ rí,’ Ukamaka sọ.

‘Ìwọ náà ò bèèrè rí.’

Ó gbé sandwich ẹ̀ sórí abọ́, ó sì jókòó ní tábílì ìjẹun. ‘Mi ò mọ̀ pé nǹkankan wà láti bèèrè. Èrò mi ni pé wàá kàn sọọ́ fún mi ni.’

Chinedu ò sọ ǹkankan.

‘Óyá, sọ fún mi. Sọ fún mi nípa ìfẹ́ yìí. Ṣé níbí ni àbí nílé?’

‘Nílé. Mo wà pẹ̀lú ọ̀dọ́mọkùnrin náà fún ó fẹ́ẹ̀ tó ọdún méjì.’

Àsìkò náà wà nídàákẹ́jẹ́ẹ́. Ukamaka mú ìnuwọ́ kan nílẹ̀, ó sì ríi pé òun ti mọ̀ látinúwá tẹ́lẹ̀, bóyá láti ìbẹ̀rẹ̀ gaan. Ṣùgbón, nítorípé ó rò pé Chinedu fẹ́ kí òun fi ìyàlẹ́nu hàn, ó ní, ‘Oh, àṣé okùnrin-afẹ́kùnrin ni ẹ́.’

‘Ẹnìkan sọ fún mi nígbàkanrí pé èmi ni ọkùnrin-afẹ́kùnrin tó jọ ọkùnrin-afẹ́bìnrin jùlọ tí òún mọ̀. Mo kórìíra ara mi fún bí mo ṣe fẹ́ràn àpéjúwe yẹn.’ Ó ń rẹ́rìín músẹ́; ara ẹ̀ẹ́ balẹ̀.

‘Óyá sọ fún mi nípa ìfẹ́ yìí.’

‘Orúkọ ọkùnrin náà ni Abídèmí. Bí Chinedu ṣe pe orúkọ yẹn, Abídèmí, jẹ́ kí Ukamaka rántíi bíi kí èèyàn gbáralé iṣan tó ń rò’yàn, ara ríró tí èèyàn ṣe fúnra ẹ, tó sì mú inú ẹ̀ dùn.

Ó sọ̀rọ̀ ní pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́, pẹ̀lúu àìkọbiara sí àwọn kókó tí Ukamaka rò pé kò ṣe pàtàkì — ṣé Ọjọ́rú ni àbí Ọjọ́bọ ni Abídèmí múu lọ sí ilé ijó aládàáni ti àwọn ọkùnrin-afẹ́kùnrin níbi tí wọ́n ti bọwọ́ pẹ̀lúu ààrẹ orílẹ̀-èdè àtijọ́ kan? — Ukamaka sì rò pé ìtàn yìí jẹ́ èyí tí kò tíì sọ púpọ̀ ní kíkún, tàbí tí kò tíì sọ fún ẹnìkankan rí.

Òṣìṣé bánkì ni Abídèmí jẹ́, ọmọ Ẹni Ńlá kan ni tó ti lọ sí yunifásitì ní Ìlú Ọba, irú ọkùnrin tó máa ń wọ bẹ́lítì aláwọ pẹ̀lú àràmọ̀ndà lógò bíi bọ́kù. Irú ìkan báyìí ló wọ̀ nígbà tó wá sí ilé iṣẹ́ onífóònù alágbèéká níbi tí Chinedu ti ń ṣiṣẹ́ aṣọ̀yàyà oníbàárà. O tiẹ̀ fẹ́ẹ̀ yájú, tó ń bèèrè pé ṣé kò sí ẹnìkan nípò àgbà t’óun lẹ̀ bá sọ̀rọ̀, ṣùgbọ́n Chinedu kò ṣe iyèméjì irú ojú tí wọ́n fún ara wọn wò, irú dídùn inú tí kò tíì rí rí láti ìgbà ìbáṣepọ̀ àkọ́kọ́ rẹ̀ pẹ̀lú atọ́kùn-ilé-ìwé fún eré ìdárayà kan nígbà tó wà ní ilé ìwé girama. Abídèmí fúun ní káàdì ẹ̀, o sì sọ ní kánmọ́, ‘Pè mí.’ Bí Abídèmí yóò ṣe darí ìbáṣepọ̀ yìí nìyẹn fún ọdún méjì tó tẹ̀lée, tó fẹ́ mọ ibi tí Chinedu lọ àti oun tó ṣe, tó ń ra mọ́tò fúun láì bèèrè lọ́wọ́ ẹ̀, tí èyí fi wà ní ipò àti máa ṣàlàyé fún ẹbí àti ọ̀rẹ́ ẹ̀ ibi tó ti ra Honda tuntun lójijì, pípèé láti tẹ̀lée lọ sí ìrìn àjò afẹ́ lọ sí Calabar àti Kaduna láìfúun ju ọjọ́ kan láti ròó lọ, àti fífi ọ̀rọ̀ burúkú ránṣẹ́ lóríi fóònù nígbà tí Chinedu ò bá rí ìpèe rẹ̀ gbé. Síbẹ̀, Chinedu fẹ́ràan dídìmọ́ni yìí, ìjípépé ìbáṣepọ̀ náà tó gba ara àwọn méjèèjì kan. Àfi ìgbà tí Abídèmí sọ pé òun ti fẹ́ gbéyàwó. Orúkọ ẹni tó fẹ́ fẹ́ ni Kẹ́mi; àwọn òbí àwọn méjèèjì sì ti mọra tipẹ́tipẹ́. Wípé wọn ò le ṣàìmáṣe ìgbéyàwó jẹ́ oun tó ti yé àwọn méjèèjì tẹ́lẹ̀. Bóyá kò sì sí oun tíì bá yàtọ̀ bí Chinedu ò bá tíì pàdé Kẹ́mi níbi ayẹyẹ àjọ̀dún ìgbéyàwó àwọn òbí Abídèmí. Kò wulẹ̀ fẹ́ lọ tẹ́lẹ̀ — ó máa ń yẹra fún àwọn ayẹyẹ ẹbí Abídèmí — ṣùgbọ́n Abídèmí ní dandan ni, wípé òun ò lè borí bí ìrọ̀lẹ́ náà ṣe gùn tó àfi tí Chinedu bá wà níbẹ̀ nìkan. Abídèmí sọ̀rọ̀ pẹ̀lú ohùn tó dàbí ohun tí a fi ẹ̀rín tẹ́lẹ̀ rẹ̀ nígbà tó fi Chinedu hàn sí Kẹ́mi gẹ́gẹ́ bíi ‘ọ̀rẹ́ mi gidi’.

‘Chinedu máa ń mu ọtí jù mí lọ,’ ni Abídèmí sọ fún Kẹ́mi tó wọ irun dídì òyìnbó àti aṣọ aláwọ̀ pupa rẹ́súrẹ́sú rẹ̀ aláìlápá. Ó jókòó lẹ́gbẹ̀ẹ́ Abídèmí, ó sì ń nawọ́ lóòrèkóòrè láti gbọn nǹkan kúrò lára bùbá rẹ̀, láti báa bu gílásì ọtí ẹ̀ kún, lái gbọ́wọ́ lée lórúnkún. Ní gbogbo ìgbà náà, gbogbo ara ẹ̀ ló dúró digbì tó bá tiẹ̀ mu, bíi ẹni tó ṣetán láti ta gìrì dìde láti ṣe ounkóun tó bá gbà láti mú inú àfẹ́sọ́nà ẹ̀ dùn. ‘O ní máà níkùn ńlá ti bíà àbí?’ Abídèmí sọ, pẹ̀lú ọwọ́ ẹ̀ lórí itan tọ̀ún: ‘Ọkùnrin yìí á ní tiẹ̀ k’émi tó ní tèmi, mo ń sọ fún ẹ.’

Chinedu rẹ́rìín músẹ́ pẹ̀lú ìnira. Orí ti bẹ̀rẹ̀ sí ń fọ́ọ. Ìbínú rẹ̀ sí Abídèmí sì ti bẹ̀rẹ̀ sí ń bú gbàmù. Bí Chinedu ṣe ń sọ èyí fún Ukamaka, bí ìbínú ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ yìí ṣe ‘fọ́ọ lórí’, Ukamaka ṣàkíyèsí bí ara ẹ̀ ṣe ti le tó.

‘Ó wù ẹ́ kó jẹ́ pé oò pàdé ìyàwó ẹ̀, ‘ Ukamaka sọ.

‘Rárá. Ó wù mí pé kó tiẹ̀ rúu lójú díẹ̀.’

‘Ó dá mi lójú pé bẹ́ẹ̀ ló rí’

‘Kò rí bẹ́ẹ̀. Mo wòó lọ́jọ́ yẹn, bó ṣe ń ṣe pẹ̀lú àwa méjèèjì níbẹ̀, tó ń mu ọdẹ́kù, tó ń ṣe yẹ̀yẹ́ nípa mi fúun àti nípa ẹ̀ fún mi, mo dẹ̀ mọ̀ pé ó máa lọ síbùsùn ẹ̀, á dẹ̀ sùn dáadáa lálẹ́. Táa bá tẹ̀síwájú ni, ó máa wá máa bá mi lọ́sàán, á dẹ̀ tún padà lọ bá òun nílé lálẹ́, á dẹ̀ sùn falala dáadáa ní gbogbo ìgbà. Ó wù mí pé kó má lè sùn dáadáa nígbà míì.’

‘O wá dẹ́kùn ẹ̀?’

‘Inú bíi gidi. Kò yée ìdí tí mi ò lè fi ṣe oun tó fẹ́.’

‘Báwo lèèyàn kan ṣe le sọ pé òún fẹ́ràn ẹ, tá dẹ̀ wá fẹ́ ṣe nǹkan tó mú inúu tiẹ̀ nìkan dùn?’ Bí Udenna ṣe rí nìyẹn.’

Chinedu rún ìrọ̀rí tó gbé lé’tan. ‘Ukamaka, kìí ṣe gbogbo nǹkan ló jọ mọ Udenna.’

‘Mo kàn ń sọ ni, pé Abídèmí dàbí Udenna díẹ̀. Bóyá irú ìfẹ́ bẹ́yẹn ò yé mi ni ṣá.’

‘Bóyá kìí ṣè’fẹ́,’ Chinedu sọ, ó sì dìde lọ́gán láti orí àga. ‘Udenna ṣe eléyìí fún ẹ, Udenna ṣe tọ̀ún fún ẹ, ṣùgbọ́n kílódé tóo fi gbà kó ṣe bẹ́ẹ̀? Kílódé tóo fi gbà fúun? Ǹjẹ́ o tiẹ̀ ti rò bóyá kìí ṣe ìfẹ́?’

Ohùn ẹ̀ mọ́rẹ́lọ́wọ́ bíi t’ọlọ́kàn líle, dídún ẹ̀, tó bẹ́ẹ̀ tí à àyàa Ukamaka já fún ìṣẹ́jú àáyá kan, kó tó ṣẹ̀ wá bínú, tó sì ní kó bọ́ síta.

 

 

____

Kọ́lá Túbọ̀sún is a linguist, writer, and scholar. His first collection of poetry Edwardsville by Heart was published by Wisdom’s Bottom Press in 2018. He is the first African awardee of the Premio Ostana, a prize given by Chambra D’Oc in Italy, to work and advocacy in the mother tongue. He lives in Lagos.

 

Ìtàn yìí ni a kọ́kọ́ tẹ̀ jáde gẹ́gẹ́ bíi The Shivering nínú ìwée Chimamanda Adichie tí a pè ní “The Thing Around Your Neck” lọ́dúun 2009.